18. Ati si angẹli ijọ ni Tiatira kọwe: Nkan wọnyi li Ọmọ Ọlọrun wi, ẹniti o ni oju rẹ̀ bi ọwọ́ iná, ti ẹsẹ rẹ̀ si dabi idẹ daradara;
19. Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, ati ifẹ rẹ, ati igbagbọ́, ati ìsin, ati sũru rẹ; ati pe iṣẹ rẹ ikẹhin jù ti iṣaju lọ.
20. Ṣugbọn eyi ni mo ri wi si ọ, nitoriti iwọ fi aye silẹ fun obinrin nì Jesebeli ti o pè ara rẹ̀ ni woli, o si nkọ awọn iranṣẹ mi o si ntan wọn lati mã ṣe àgbere, ati lati mã jẹ ohun ti a pa rubọ si oriṣa.
21. Emi si fi sã fun u lati ronupiwada; kò si fẹ ronupiwada agbere rẹ̀.