Ifi 2:17-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Ẹniti o ba li etí, ki o gbọ́ ohun ti Ẹmí nsọ fun awọn ijọ. Ẹniti o ba ṣẹgun li emi o fi manna ti o pamọ́ fun jẹ, emi o si fun u li okuta funfun kan, ati sara okuta na orukọ titun ti a o kọ si i, ti ẹnikẹni kò mọ̀ bikoṣe ẹniti o gbà a.

18. Ati si angẹli ijọ ni Tiatira kọwe: Nkan wọnyi li Ọmọ Ọlọrun wi, ẹniti o ni oju rẹ̀ bi ọwọ́ iná, ti ẹsẹ rẹ̀ si dabi idẹ daradara;

19. Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, ati ifẹ rẹ, ati igbagbọ́, ati ìsin, ati sũru rẹ; ati pe iṣẹ rẹ ikẹhin jù ti iṣaju lọ.

20. Ṣugbọn eyi ni mo ri wi si ọ, nitoriti iwọ fi aye silẹ fun obinrin nì Jesebeli ti o pè ara rẹ̀ ni woli, o si nkọ awọn iranṣẹ mi o si ntan wọn lati mã ṣe àgbere, ati lati mã jẹ ohun ti a pa rubọ si oriṣa.

21. Emi si fi sã fun u lati ronupiwada; kò si fẹ ronupiwada agbere rẹ̀.

22. Kiyesi i, emi ó gbe e sọ si ori akete, ati awọn ti mba a ṣe panṣaga li emi o fi sinu ipọnju nla, bikoṣe bi nwọn ba ronupiwada iṣẹ wọn.

Ifi 2