13. Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, ati ibiti iwọ ngbé, ani ibiti ìtẹ Satani wà: ati pe iwọ dì orukọ mi mu ṣinṣin, ti iwọ kò si sẹ́ igbagbọ́ mi, li ọjọ wọnni ninu eyi ti Antipa iṣe olõtọ ajẹrikú mi, ẹniti nwọn pa ninu nyin, nibiti Satani ngbé.
14. Ṣugbọn mo ni nkan diẹ iwi si ọ, nitoriti iwọ ni awọn ti o dì ẹkọ́ ti Balaamu mu nibẹ̀, ẹniti o kọ́ Balaku lati mu ohun ikọsẹ̀ wá siwaju awọn ọmọ Israeli, lati mã jẹ ohun ti a pa rubọ si oriṣa, ati lati mã ṣe àgbere.
15. Bẹ̃ni iwọ si ní awọn ti o gbà ẹkọ awọn Nikolaitani pẹlu, ohun ti mo korira.
16. Ronupiwada; bikoṣe bẹ̃ emi ó tọ̀ ọ wá nisisiyi, emi o si fi idà ẹnu mi ba wọn jà.
17. Ẹniti o ba li etí, ki o gbọ́ ohun ti Ẹmí nsọ fun awọn ijọ. Ẹniti o ba ṣẹgun li emi o fi manna ti o pamọ́ fun jẹ, emi o si fun u li okuta funfun kan, ati sara okuta na orukọ titun ti a o kọ si i, ti ẹnikẹni kò mọ̀ bikoṣe ẹniti o gbà a.
18. Ati si angẹli ijọ ni Tiatira kọwe: Nkan wọnyi li Ọmọ Ọlọrun wi, ẹniti o ni oju rẹ̀ bi ọwọ́ iná, ti ẹsẹ rẹ̀ si dabi idẹ daradara;
19. Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, ati ifẹ rẹ, ati igbagbọ́, ati ìsin, ati sũru rẹ; ati pe iṣẹ rẹ ikẹhin jù ti iṣaju lọ.
20. Ṣugbọn eyi ni mo ri wi si ọ, nitoriti iwọ fi aye silẹ fun obinrin nì Jesebeli ti o pè ara rẹ̀ ni woli, o si nkọ awọn iranṣẹ mi o si ntan wọn lati mã ṣe àgbere, ati lati mã jẹ ohun ti a pa rubọ si oriṣa.