1. SI angẹli ijọ ni Efesu kọwe: Nkan wọnyi li ẹniti o mu irawọ meje na li ọwọ́ ọtún rẹ̀, ẹniti nrìn li arin ọpá wura fitila meje na wipe,
2. Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, ati lãlã rẹ, ati ìfarada rẹ, ati bi ara rẹ kò ti gba awọn ẹni buburu: ati bi iwọ si ti dan awọn ti npè ara wọn ni aposteli, ti nwọn kì sì iṣe bẹ̃ wo, ti iwọ si ri pe eleke ni wọn;
3. Ti iwọ si farada ìya, ati nitori orukọ mi ti o si fi aiya rán, ti ãrẹ̀ kò si mu ọ.
4. Ṣugbọn eyi ni mo ri wi si ọ, pe, iwọ ti fi ifẹ rẹ iṣaju silẹ.
5. Nitorina ranti ibiti iwọ gbé ti ṣubu, ki o si ronupiwada, ki o si ṣe iṣẹ iṣaju; bi kò si ṣe bẹ̃, emi ó si tọ̀ ọ wá, emi o si ṣí ọpá fitila rẹ kuro ni ipò rẹ̀, bikoṣe bi iwọ ba ronupiwada.
6. Ṣugbọn eyi ni iwọ ní, pe iwọ korira iṣe awọn Nikolaitani eyiti emi pẹlu si korira.
7. Ẹniti o ba li etí ki o gbọ́ ohun ti Ẹmí nsọ fun awọn ijọ. Ẹniti o ba ṣẹgun ni emi o fi eso igi ìye nì fun jẹ, ti mbẹ larin Paradise Ọlọrun.
8. Ati si angẹli ijọ ni Smirna kọwe: Nkan wọnyi li ẹniti iṣe ẹni-iṣaju ati ẹni-ikẹhin wi, ẹniti o ti kú, ti o si tun yè:
9. Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, ati ipọnju, ati aini rẹ (ṣugbọn ọlọ́rọ̀ ni ọ) emi si mọ̀ ọ̀rọ-òdi si Ọlọrun ti awọn ti nwipe Ju li awọn tikarawọn, ti nwọn kì sì iṣe bẹ̃, ṣugbọn ti nwọn jẹ́ sinagogu ti Satani.
10. Máṣe bẹ̀ru ohunkohun tì iwọ mbọ̀ wá jiya rẹ̀: kiyesi i, Èṣu yio gbé ninu nyin jù sinu tubu, ki a le dán nyin wò; ẹnyin o si ni ipọnju ni ijọ mẹwa: iwọ sa ṣe olõtọ de oju ikú, emi ó si fi ade ìye fun ọ.
11. Ẹniti o ba li etí, ki o gbọ́ ohun ti Ẹmí nsọ fun awọn ijọ. Ẹniti o ba ṣẹgun kì yio farapa ninu ikú keji.
12. Ati si angẹli ijọ ni Pergamu kọwe: Nkan wọnyi li ẹniti o ni idà mimu oloju meji nì wipe,