1. LẸHIN nkan wọnyi mo si ri angẹli miran, o nti ọrun sọkalẹ wá ti on ti agbara nla; ilẹ aiye si ti ipa ogo rẹ̀ mọlẹ.
2. O si kigbe li ohùn rara, wipe, Babiloni nla ṣubu, o ṣubu, o si di ibujoko awọn ẹmi èṣu, ati ihò ẹmí aimọ́ gbogbo, ati ile ẹiyẹ aimọ́ gbogbo, ati ti ẹiyẹ irira.
3. Nitori nipa ọti-waini irunu àgbere rẹ̀ ni gbogbo awọn orilẹ-ede ṣubu, awọn ọba aiye si ti ba a ṣe àgbere, ati awọn oniṣowo aiye si di ọlọrọ̀ nipa ọ̀pọlọpọ wọbia rẹ̀.
4. Mo si gbọ́ ohùn miran lati ọrun wá, nwipe, Ẹ ti inu rẹ̀ jade, ẹnyin enia mi, ki ẹ má bã ṣe alabapin ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ki ẹ má bã si ṣe gbà ninu iyọnu rẹ̀.
5. Nitori awọn ẹ̀ṣẹ rẹ̀ gá ani de ọrun, Ọlọrun si ti ranti aiṣedẽdẽ rẹ̀.
6. San a fun u, ani bi on ti san fun-ni, ki o si ṣe e ni ilọpo meji fun u gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀: ninu ago na ti o ti kùn, on ni ki ẹ si kún fun u ni meji.
7. Niwọn bi o ti yin ara rẹ̀ logo to, ti o si huwa wọbia, niwọn bẹ̃ ni ki ẹ da a loro ki ẹ si fún u ni ibanujẹ: nitoriti o wi li ọkàn rẹ̀ pe, mo joko bi ọbabirin, emi kì si iṣe opó, emi ki yio si ri ibinujẹ lai.