8. Ẹranko ti iwọ ri nì, o ti wà, kò si sí mọ́: yio si ti inu ọgbun gòke wá, yio si lọ sinu egbé: ẹnu yio si yà awọn ti ngbé ori ilẹ aiye, orukọ awọn ẹniti a kò ti kọ sinu iwe ìye lati ipilẹṣẹ aiye, nigbati nwọn nwò ẹranko ti o ti wà, ti kò si sí mọ́, ti o si mbọ̀wá.
9. Nihin ní itumọ ti o li ọgbọ́n wà. Ori meje nì oke nla meje ni, lori eyi ti obinrin na joko.
10. Ọba meje si ni nwọn: awọn marun ṣubu, ọkan mbẹ, ọkan iyokù kò si ti ide; nigbati o ba si de, yio duro fun igba kukuru.
11. Ẹranko ti o si ti wà, ti kò si si, on na si ni ẹkẹjọ, o si ti inu awọn meje na wá, o si lọ si iparun.
12. Iwo mẹwa ti iwọ si ri nì ọba mẹwa ni nwọn, ti nwọn kò iti gba ijọba; ṣugbọn nwọn gba ọla bi ọba pẹlu ẹranko na fun wakati kan.
13. Awọn wọnyi ni inu kan, nwọn o si fi agbara ati ọla wọn fun ẹranko na.
14. Awọn wọnyi ni yio si mã ba Ọdọ-Agutan jagun, Ọdọ-Agutan na yio si ṣẹgun wọn: nitori on ni Oluwa awọn oluwa, ati Ọba awọn ọba: awọn ti o si wà pẹlu rẹ̀, ti a pè, ti a yàn, ti nwọn si jẹ olõtọ yio si ṣẹgun pẹlu.
15. O si wi fun mi pe, Awọn omi ti iwọ ri nì, nibiti àgbere nì joko, awọn enia ati ẹya ati orilẹ ati oniruru ède ni wọn.