11. Ẹranko ti o si ti wà, ti kò si si, on na si ni ẹkẹjọ, o si ti inu awọn meje na wá, o si lọ si iparun.
12. Iwo mẹwa ti iwọ si ri nì ọba mẹwa ni nwọn, ti nwọn kò iti gba ijọba; ṣugbọn nwọn gba ọla bi ọba pẹlu ẹranko na fun wakati kan.
13. Awọn wọnyi ni inu kan, nwọn o si fi agbara ati ọla wọn fun ẹranko na.
14. Awọn wọnyi ni yio si mã ba Ọdọ-Agutan jagun, Ọdọ-Agutan na yio si ṣẹgun wọn: nitori on ni Oluwa awọn oluwa, ati Ọba awọn ọba: awọn ti o si wà pẹlu rẹ̀, ti a pè, ti a yàn, ti nwọn si jẹ olõtọ yio si ṣẹgun pẹlu.
15. O si wi fun mi pe, Awọn omi ti iwọ ri nì, nibiti àgbere nì joko, awọn enia ati ẹya ati orilẹ ati oniruru ède ni wọn.
16. Ati iwo mẹwa ti iwọ ri, ati ẹranko na, awọn wọnyi ni yio korira àgbere na, nwọn o si sọ ọ di ahoro ati ẹni ìhoho, nwọn o si jẹ ẹran ara rẹ̀, nwọn o si fi iná sun u patapata.
17. Nitori Ọlọrun ti fi sinu ọkàn wọn lati mu ifẹ rẹ̀ ṣẹ, lati ni inu kan, ati lati fi ijọba wọn fun ẹranko na, titi ọ̀rọ Ọlọrun yio fi ṣẹ.
18. Obinrin ti iwọ ri ni ilu nla nì, ti njọba lori awọn ọba ilẹ aiye.