1. ỌKAN ninu awọn angẹli meje na ti o ni ìgo meje wọnni si wá, o si ba mi sọrọ wipe, Wá nihin; emi o si fi idajọ àgbere nla nì ti o joko lori omi pupọ̀ han ọ:
2. Ẹniti awọn ọba aiye ba ṣe àgbere, ti a si ti fi ọti-waini àgbere rẹ̀ pa awọn ti ngbe inu aiye.
3. O si gbe mi ninu Ẹmí lọ si aginjù: mo si ri obinrin kan o joko lori ẹranko alawọ̀ odòdó kan ti o kún fun orukọ ọrọ-odi, o ni ori meje ati iwo mẹwa.
4. A si fi aṣọ elese aluko ati aṣọ odòdó wọ obinrin na, a si fi wura ati okuta iyebiye ati perli ṣe e lọṣọ́, o ni ago wura kan li ọwọ́ rẹ̀, ti o kún fun irira ati fun ẹgbin àgbere rẹ̀: