15. Kiyesi i, mo mbọ̀ bi olè. Ibukún ni fun ẹniti nṣọna, ti o si npa aṣọ rẹ̀ mọ́, ki o má bã rìn ni ìhoho, nwọn a si ri itiju rẹ̀.
16. O si gbá wọn jọ si ibikan ti a npè ni Har-mageddoni li ède Heberu.
17. Ekeje si tú ìgo tirẹ̀ si oju ọrun; ohùn nla kan si ti inu tẹmpili jade lati ibi itẹ́, wipe, O pari.
18. Mànamána si kọ, a si gbọ́ ohùn, ãrá si san, ìṣẹlẹ nla si ṣẹ̀, iru eyiti kò ṣẹ̀ ri lati igbati enia ti wà lori ilẹ, iru ìṣẹlẹ nla bẹ̃, ti o si lagbara tobẹ̃.
19. Ilu nla na si pin si ipa mẹta, awọn orilẹ-ède si ṣubu: Babiloni nla si wá si iranti niwaju Ọlọrun, lati fi ãgo ọti-waini ti irunu ibinu rẹ̀ fun u.
20. Olukuluku erekuṣu si salọ, a kò si ri awọn òke nla mọ́.
21. Yinyín nla, ti ọkọ̃kan rẹ̀ to talenti ni ìwọ̀n, si bọ́ lù awọn enia lati ọrun wà: awọn enia si sọ̀rọ-òdi si Ọlọrun nitori iyọnu yinyín na; nitoriti iyọnu rẹ̀ na pọ̀ gidigidi.