Ifi 15:4-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Tani kì yio bẹ̀ru, Oluwa, ti kì yio si fi ogo fun orukọ rẹ? nitori iwọ nikanṣoṣo ni mimọ́: gbogbo awọn orilẹ-ède ni yio si wá, ti yio si foribalẹ niwaju rẹ; nitori a ti fi idajọ rẹ hàn.

5. Lẹhin na mo si wò, si kiyesi i, a ṣí tẹmpili agọ́ ẹrí li ọrun silẹ:

6. Awọn angẹli meje na si ti inu tẹmpili jade wá, nwọn ni iyọnu meje nì, a wọ̀ wọn li aṣọ ọgbọ funfun ti ndan, a si fi àmure wura dì wọn li õkan àiya.

7. Ati ọkan ninu awọn ẹda alãye mẹrin nì fi ìgo wura meje fun awọn angẹli meje na, ti o kún fun ibinu Ọlọrun, ẹniti mbẹ lãye lai ati lailai.

8. Tẹmpili na si kún fun ẹ̃fin lati inu ogo Ọlọrun ati agbara rẹ̀ wá; ẹnikẹni kò si le wọ̀ inu tẹmpili na lọ titi a fi mu iyọnu mejeje awọn angẹli meje na ṣẹ.

Ifi 15