Ifi 14:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Mo si wò, si kiyesi i, Ọdọ-Agutan na duro lori òke Sioni, ati pẹlu rẹ̀ ọkẹ́ meje o le ẹgbaji enia, nwọn ni orukọ rẹ̀, ati orukọ Baba rẹ̀ ti a kọ si iwaju wọn.

2. Mo si gbọ́ ohùn kan lati ọrun wá, bi ariwo omi pupọ̀, ati bi sisán ãrá nla: mo si gbọ́ awọn aludùru, nwọn nlù dùru wọn:

3. Nwọn si nkọ bi ẹnipe orin titun niwaju itẹ́ nì, ati niwaju awọn ẹda alãye mẹrin nì, ati awọn àgba nì: ko si si ẹniti o le kọ́ orin na, bikoṣe awọn ọkẹ́ meje o le ẹgbaji enia, ti a ti rà pada lati inu aiye wá.

4. Awọn wọnyi li a kò fi obinrin sọ di ẽri; nitoripe wundia ni nwọn. Awọn wọnyi ni ntọ̀ Ọdọ-Agutan na lẹhin nibikibi ti o ba nlọ. Awọn wọnyi li a rà pada lati inu awọn enia wá, nwọn jẹ́ akọso fun Ọlọrun ati fun Ọdọ-Agutan na.

5. A kò si ri eke li ẹnu wọn, nwọn jẹ alailabuku.

6. Mo si ri angẹli miran nfò li agbedemeji ọrun, ti on ti ihinrere ainipẹkun lati wãsu fun awọn ti ngbé ori ilẹ aiye, ati fun gbogbo orilẹ, ati ẹya, ati ède, ati enia,

Ifi 14