1. Mo si wò, si kiyesi i, Ọdọ-Agutan na duro lori òke Sioni, ati pẹlu rẹ̀ ọkẹ́ meje o le ẹgbaji enia, nwọn ni orukọ rẹ̀, ati orukọ Baba rẹ̀ ti a kọ si iwaju wọn.
2. Mo si gbọ́ ohùn kan lati ọrun wá, bi ariwo omi pupọ̀, ati bi sisán ãrá nla: mo si gbọ́ awọn aludùru, nwọn nlù dùru wọn:
3. Nwọn si nkọ bi ẹnipe orin titun niwaju itẹ́ nì, ati niwaju awọn ẹda alãye mẹrin nì, ati awọn àgba nì: ko si si ẹniti o le kọ́ orin na, bikoṣe awọn ọkẹ́ meje o le ẹgbaji enia, ti a ti rà pada lati inu aiye wá.