Ifi 12:7-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Ogun si mbẹ li ọrun: Mikaeli ati awọn angẹli rẹ̀ ba dragoni na jàgun; dragoni si jàgun ati awọn angẹli rẹ̀.

8. Nwọn kò si le ṣẹgun; bẹ̃ni a kò si ri ipo wọn mọ́ li ọrun.

9. A si lé dragoni nla na jade, ejò lailai nì, ti a npè ni Èṣu, ati Satani, ti ntàn gbogbo aiye jẹ, a si lé e jù si ilẹ aiye, a si le awọn angẹli rẹ̀ jade pẹlu rẹ̀.

10. Mo si gbọ́ ohùn rara li ọrun, nwipe, Nigbayi ni igbala de, ati agbara, ati ijọba Ọlọrun wa, ati ọla ti Kristi rẹ̀; nitori a ti lé olufisùn awọn arakunrin wa jade, ti o nfi wọn sùn niwaju Ọlọrun wa lọsán ati loru.

11. Nwọn si ṣẹgun rẹ̀ nitori ẹ̀jẹ Ọdọ-Agutan na, ati nitori ọ̀rọ ẹrí wọn, nwọn kò si fẹran ẹmi wọn ani titi de ikú.

12. Nitorina ẹ mã yọ̀, ẹnyin ọrun, ati ẹnyin ti ngbé inu wọn. Egbé ni fun aiye ati fun okun! nitori Èṣu sọkalẹ tọ̀ nyin wá ni ibinu nla, nitori o mọ̀ pe ìgba kukuru ṣá li on ni.

13. Nigbati dragoni na ri pe a lé on lọ si ilẹ aiye, o ṣe inunibini si obinrin ti o bí ọmọkunrin na.

14. A si fi apá iyẹ́ meji ti idì nla na fun obinrin na, pe ki o fò lọ si aginjù, si ipò rẹ̀, nibiti a gbé bọ́ ọ fun akoko kan ati fun awọn akoko, ati fun idaji akoko kuro lọdọ ejò na.

Ifi 12