5. Angẹli na ti mo ri ti o duro lori okun ati lori ilẹ, si gbé ọwọ́ rẹ̀ si oke ọrun,
6. O si fi ẹniti mbẹ lãye lai ati lailai búra, ẹniti o dá ọrun, ati ohun ti mbẹ ninu rẹ̀, ati ilẹ aiye, ati ohun ti mbẹ ninu rẹ̀, ati okun, ati ohun ti mbẹ ninu rẹ̀, pe ìgba kì yio si mọ́:
7. Ṣugbọn li ọjọ ohùn angẹli keje, nigbati yio ba fun ipe, nigbana li ohun ijinlẹ Ọlọrun pari, gẹgẹ bi ihinrere ti o sọ fun awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn woli.
8. Ohùn na ti mo gbọ́ lati ọrun wá tún mba mi sọrọ, o si wipe, Lọ, gbà iwe ti o ṣí nì lọwọ angẹli ti o duro lori okun ati lori ilẹ.
9. Mo si tọ̀ angẹli na lọ, mo si wi fun u pe, Fun mi ni iwe kekere nì. O si wi fun mi pe, Gbà ki o si jẹ ẹ tan; yio mu inu rẹ korò, ṣugbọn li ẹnu rẹ yio dabi oyin.
10. Mo si gbà iwe kekere na li ọwọ́ angẹli na, mo si jẹ ẹ tan; o si dùn li ẹnu mi bi oyin: bi mo si ti jẹ ẹ tan, inu mi korò.
11. A si wi fun mi pe, Iwọ o tún sọ asọtẹlẹ lori ọpọlọpọ enia, ati orilẹ, ati ède, ati awọn ọba.