Ifi 10:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. MO si ri angẹli miran alagbara o nti ọrun sọkalẹ wá, a fi awọsanma wọ̀ ọ li aṣọ: oṣumare si mbẹ li ori rẹ̀, oju rẹ̀ si dabi õrùn, ati ẹsẹ rẹ̀ bi ọwọ̀n iná:

2. O si ni iwe kekere kàn ti a ṣi li ọwọ́ rẹ̀: o si fi ẹsẹ rẹ̀ ọtun le okun, ati ẹsẹ rẹ̀ òsi le ilẹ,

3. O si ke li ohùn rara, bi igbati kiniun ba bú ramuramu: nigbati o si ké, awọn ãrá meje na fọhun.

4. Nigbati awọn ãrá meje na fọhun, mo mura ati kọwe: mo si gbọ́ ohùn lati ọrun wá nwi fun mi pe, Fi èdidi dí ohun ti awọn ãrá meje na sọ, má si ṣe kọ wọn silẹ.

Ifi 10