14. Ori rẹ̀ ati irun rẹ̀ funfun bi ẹ̀gbọn owu, o funfun bi sno; oju rẹ̀ si dabi ọwọ́ iná;
15. Ẹsẹ rẹ̀ si dabi idẹ daradara, bi ẹnipe a dà a ninu ileru; ohùn rẹ̀ si dabi iró omi pupọ̀.
16. O si ni irawọ meje li ọwọ́ ọtún rẹ̀; ati lati ẹnu rẹ̀ wá ni idà oloju meji mimú ti jade: oju rẹ̀ si dabi õrùn ti o nfi agbara rẹ̀ ràn.
17. Nigbati mo ri i, mo wolẹ li ẹsẹ rẹ̀ bi ẹniti o kú. O si fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ le mi, o nwi fun mi pe, Máṣe bẹ̀ru; Emi ni ẹni-iṣaju ati ẹni-ikẹhin:
18. Emi li ẹniti o mbẹ lãye, ti o si ti kú; si kiyesi i, emi si mbẹ lãye si i titi lai, Amin; mo si ní kọkọrọ ikú ati ti ipo-oku.
19. Kọwe ohun gbogbo ti iwọ ti ri, ati ti ohun ti mbẹ, ati ti ohun ti yio hù lẹhin eyi;
20. Ohun ijinlẹ ti irawọ meje na ti iwọ ri li ọwọ́ ọtún mi, ati ọpá wura fitila meje na. Irawọ meje ni awọn angẹli ìjọ meje na: ati ọpá fitila meje na ti iwọ ri ni awọn ijọ meje.