O nwipe, Emi ni Alfa ati Omega, ẹni-iṣaju ati ẹni-ikẹhin: ohun ti iwọ ba si ri, kọ ọ sinu iwe, ki o si rán a si awọn ijọ meje; si Efesu, ati si Smirna, ati si Pergamu, ati si Tiatira, ati si Sardi, ati si Filadelfia, ati si Laodikea.