1. IFIHÀN ti Jesu Kristi, ti Ọlọrun fifun u, lati fihàn fun awọn iranṣẹ rẹ̀ ohun ti kò le ṣaiṣẹ ni lọ̃lọ; o si ranṣẹ o si fi i hàn lati ọwọ́ angẹli rẹ̀ wá fun Johanu, iranṣẹ rẹ̀:
2. Ẹniti o jẹri ọ̀rọ Ọlọrun, ati ẹrí Jesu Kristi, ati ti ohun gbogbo ti o ri.
3. Olubukún li ẹniti nkà, ati awọn ti o ngbọ́ ọ̀rọ isọtẹlẹ yi, ti o si npa nkan wọnni ti a kọ sinu rẹ̀ mọ́: nitori igba kù si dẹ̀dẹ.
4. JOHANU si ìjọ meje ti mbẹ ni Asia: Ore-ọfẹ fun nyin, ati alafia, lati ọdọ ẹniti o mbẹ, ti o si ti wà, ti o si mbọ̀wá; ati lati ọdọ awọn Ẹmí meje ti mbẹ niwaju itẹ́ rẹ̀;