Peteru si dide, o si bá wọn lọ. Nigbati o de, nwọn mu u lọ si yara oke na: gbogbo awọn opó si duro tì i, nwọn nsọkun, nwọn si nfi ẹ̀wu ati aṣọ ti Dorka dá hàn a, nigbati o wà pẹlu wọn.