Iṣe Apo 5:30-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

30. Ọlọrun awọn baba wa ji Jesu dide, ẹniti ẹnyin pa, tí ẹnyin si gbe kọ́ sori igi.

31. On li Ọlọrun fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ gbéga lati jẹ Ọmọ alade ati Olugbala, lati fi ironupiwada fun Israeli, ati idariji ẹ̀ṣẹ.

32. Awa si li ẹlẹri nkan wọnyi; ati Ẹmí Mimọ́ pẹlu, ti Ọlọrun fifun awọn ti o gbọ́ tirẹ̀.

Iṣe Apo 5