10. O si ṣubu lulẹ li ẹsẹ rẹ̀ lojukanna, o si kú: awọn ọdọmọkunrin si wọle, nwọn bá a o kú, nwọn si gbé e jade, nwọn sin i lẹba ọkọ rẹ̀.
11. Ẹru nla si ba gbogbo ijọ, ati gbogbo awọn ti o gbọ́ nkan wọnyi.
12. A si ti ọwọ́ awọn aposteli ṣe iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu pipọ lãrin awọn enia: gbogbo wọn si fi ọkàn kan wà ni iloro Solomoni.
13. Ninu awọn iyokù ẹnikan kò daṣà ati dapọ mọ wọn: ṣugbọn enia nkókiki wọn.
14. A si nyàn awọn ti o gbà Oluwa gbọ kun wọn si i, ati ọkunrin ati obinrin;
15. Tobẹ̃ ti nwọn ngbé awọn abirùn jade si igboro, ti nwọn ntẹ́ wọn si ori akete ati ohun ibĩrọgbọku, pe bi Peteru ba nkọja ki ojiji rẹ̀ tilẹ le ṣijibò omiran ninu wọn.
16. Ọ̀pọ enia si ko ara wọn jọ lati awọn ilu ti o yi Jerusalemu ka, nwọn nmu awọn abirùn wá, ati awọn ti ara kan fun ẹmi aimọ́: a si ṣe dida ara olukuluku wọn.
17. Ṣugbọn olori alufa dide, ti on ti gbogbo awọn ti nwọn wà lọdọ rẹ̀ (ti iṣe ẹya ti awọn Sadusi), nwọn si kún fun owu.
18. Nwọn si nawọ́ mu awọn aposteli, nwọn si fi wọn sinu tubu.
19. Ṣugbọn angẹli Oluwa ṣí ilẹkun tubu li oru; nigbati o si mu wọn jade, o wipe,
20. Ẹ lọ, ẹ duro, ki ẹ si mã sọ gbogbo ọ̀rọ iye yi fun awọn enia ni tẹmpili.
21. Nigbati nwọn si gbọ́ yi, nwọn wọ̀ tẹmpili lọ ni kutukutu, nwọn si nkọ́ni. Ṣugbọn olori alufa de, ati awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀, nwọn si pè apejọ igbimọ, ati gbogbo awọn agbàgba awọn ọmọ Israeli, nwọn si ranṣẹ si ile tubu lati mu wọn wá.
22. Ṣugbọn nigbati awọn onṣẹ de ibẹ̀, nwọn kò si ri wọn ninu tubu, nwọn pada wá, nwọn si sọ pe,