1. NJẸ Peteru on Johanu jumọ ngòke lọ si tẹmpili ni wakati adura, ti iṣe wakati kẹsan ọjọ.
2. Nwọn si gbé ọkunrin kan ti o yarọ lati inu iya rẹ̀ wá, ti nwọn ima gbé kalẹ li ojojumọ́ li ẹnu-ọna tẹmpili ti a npè ni Daradara, lati mã ṣagbe lọwọ awọn ti nwọ̀ inu tẹmpili lọ;
3. Nigbati o ri Peteru on Johanu bi nwọn ti fẹ wọ̀ inu tẹmpili, o ṣagbe.
4. Peteru si tẹjumọ́ ọ, pẹlu Johanu, o ni, Wò wa.
5. O si fiyesi wọn, o nreti ati ri nkan gbà lọwọ wọn.