Iṣe Apo 26:29-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

29. Paulu si wipe, Iba wu Ọlọrun, yala pẹlu ãpọn diẹ tabi pipọ pe, ki o maṣe iwọ nikan, ṣugbọn ki gbogbo awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ mi loni pẹlu le di iru enia ti emi jẹ laisi ẹwọn wọnyi.

30. Nigbati o si sọ nkan wọnyi tan, ọba dide, ati bãlẹ, ati Bernike, ati awọn ti o ba wọn joko:

31. Nigbati nwọn lọ si apakan, nwọn ba ara wọn sọ pe, ọkunrin yi kò ṣe nkankan ti o yẹ si ikú tabi si ẹ̀wọn.

32. Agrippa si wi fun Festu pe, A ba dá ọkunrin yi silẹ ibamaṣepe kò ti fi ọ̀ran rẹ̀ lọ Kesari.

Iṣe Apo 26