3. Ju li emi iṣe ẹniti a bí ni Tarsu ilu kan ni Kilikia, ṣugbọn ti a tọ́ ni ilu yi, li ẹsẹ Gamalieli, ti a kọ́ gẹgẹ bi lile ofin awọn baba wa, ti mo si jẹ onitara fun Ọlọrun ani gẹgẹ bi gbogbo nyin ti ri li oni.
4. Mo si ṣe inunibini si Ọna yi titi o fi de iku, mo ndè, mo si nfi wọn sinu tubu, ati ọkunrin ati obinrin.
5. Bi olori alufa pẹlu ti jẹ mi li ẹri, ati gbogbo ajọ awọn alàgba: lọwọ awọn ẹniti mo si gbà iwe lọ sọdọ awọn arakunrin, ti mo si lọ si Damasku lati mu awọn ti o wà nibẹ̀ ni didè wá si Jerusalemu, lati jẹ wọn niyà.
6. O si ṣe, bi emi ti nlọ, ti mo si sunmọ eti Damasku niwọn ọjọkanri, li ojijì, imọlẹ nla mọ́ ti ọrun wá yi mi ká.