Iṣe Apo 15:33-41 Yorùbá Bibeli (YCE)

33. Nigbati nwọn si pẹ diẹ, awọn arakunrin jọwọ wọn lọwọ lọ li alafia si ọdọ awọn ti o ran wọn.

34. Ṣugbọn o wù Sila lati gbé ibẹ̀.

35. Paulu on Barnaba si duro diẹ ni Antioku, nwọn nkọ́ni, nwọn si nwasu ọ̀rọ Oluwa, ati awọn pipọ miran pẹlu wọn.

36. Lẹhin ijọ melokan, Paulu si sọ fun Barnaba pe, Jẹ ki a tún pada lọ íbẹ awọn arakunrin wa wò, bi nwọn ti nṣe, ni ilu gbogbo ti awa ti wasu ọ̀rọ Oluwa.

37. Barnaba si pinnu rẹ̀ lati mu Johanu lọ pẹlu wọn, ẹniti apele rẹ̀ jẹ Marku.

38. Ṣugbọn Paulu rò pe, kò yẹ lati mu u lọ pẹlu wọn, ẹniti o fi wọn silẹ ni Pamfilia, ti kò si ba wọn lọ si iṣẹ na.

39. Ìja na si pọ̀ tobẹ̃, ti nwọn yà ara wọn si meji: nigbati Barnaba si mu Marku, o ba ti ọkọ̀ lọ si Kipru;

40. Ṣugbọn Paulu yàn Sila, o si lọ, bi a ti fi i lé ore-ọfẹ Oluwa lọwọ lati ọdọ awọn arakunrin.

41. O si là Siria on Kilikia lọ, o nmu ijọ li ọkàn le.

Iṣe Apo 15