Iṣe Apo 15:32-38 Yorùbá Bibeli (YCE)

32. Bi Juda on Sila tikarawọn ti jẹ woli pẹlu, nwọn fi ọ̀rọ pipọ gbà awọn arakunrin niyanju, nwọn si mu wọn li ọkàn le.

33. Nigbati nwọn si pẹ diẹ, awọn arakunrin jọwọ wọn lọwọ lọ li alafia si ọdọ awọn ti o ran wọn.

34. Ṣugbọn o wù Sila lati gbé ibẹ̀.

35. Paulu on Barnaba si duro diẹ ni Antioku, nwọn nkọ́ni, nwọn si nwasu ọ̀rọ Oluwa, ati awọn pipọ miran pẹlu wọn.

36. Lẹhin ijọ melokan, Paulu si sọ fun Barnaba pe, Jẹ ki a tún pada lọ íbẹ awọn arakunrin wa wò, bi nwọn ti nṣe, ni ilu gbogbo ti awa ti wasu ọ̀rọ Oluwa.

37. Barnaba si pinnu rẹ̀ lati mu Johanu lọ pẹlu wọn, ẹniti apele rẹ̀ jẹ Marku.

38. Ṣugbọn Paulu rò pe, kò yẹ lati mu u lọ pẹlu wọn, ẹniti o fi wọn silẹ ni Pamfilia, ti kò si ba wọn lọ si iṣẹ na.

Iṣe Apo 15