26. Awọn ọkunrin ti o fi ẹmí wọn wewu nitori orukọ Oluwa wa Jesu Kristi.
27. Nitorina awa rán Juda on Sila, awọn ti yio si fi ọ̀rọ ẹnu sọ ohun kanna fun nyin.
28. Nitori o dara loju Ẹmi Mimọ́, ati loju wa, ki a máṣe dì ẹrù kà nyin, jù nkan ti a ko le ṣe alaiṣe wọnyi lọ:
29. Ki ẹnyin ki o fà sẹhin kuro ninu ẹran apabọ oriṣa, ati ninu ẹ̀jẹ ati ninu ohun ilọlọrun-pa, ati ninu àgbere: ninu ohun ti, bi ẹnyin ba pa ara nyin mọ́ kuro, ẹnyin ó ṣe rere. Alafia.
30. Njẹ nigbati nwọn si jọwọ wọn lọwọ lọ, nwọn sọkalẹ wá si Antioku: nigbati nwọn si pè apejọ, nwọn fi iwe na fun wọn.
31. Nigbati nwọn si kà a, nwọn yọ̀ fun itunu na.
32. Bi Juda on Sila tikarawọn ti jẹ woli pẹlu, nwọn fi ọ̀rọ pipọ gbà awọn arakunrin niyanju, nwọn si mu wọn li ọkàn le.
33. Nigbati nwọn si pẹ diẹ, awọn arakunrin jọwọ wọn lọwọ lọ li alafia si ọdọ awọn ti o ran wọn.
34. Ṣugbọn o wù Sila lati gbé ibẹ̀.
35. Paulu on Barnaba si duro diẹ ni Antioku, nwọn nkọ́ni, nwọn si nwasu ọ̀rọ Oluwa, ati awọn pipọ miran pẹlu wọn.
36. Lẹhin ijọ melokan, Paulu si sọ fun Barnaba pe, Jẹ ki a tún pada lọ íbẹ awọn arakunrin wa wò, bi nwọn ti nṣe, ni ilu gbogbo ti awa ti wasu ọ̀rọ Oluwa.
37. Barnaba si pinnu rẹ̀ lati mu Johanu lọ pẹlu wọn, ẹniti apele rẹ̀ jẹ Marku.