Iṣe Apo 15:15-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Ati eyiyi li ọ̀rọ awọn woli ba ṣe dede; bi a ti kọwe rẹ̀ pe,

16. Lẹhin nkan wọnyi li emi o pada, emi o si tún agọ́ Dafidi pa ti o ti wó lulẹ; emi ó si tún ahoro rẹ̀ kọ́, emi ó si gbé e ró:

17. Ki awọn enia iyokù le mã wá Oluwa, ati gbogbo awọn Keferi lara ẹniti a npè orukọ mi,

18. Li Oluwa wi, ẹniti o sọ gbogbo nkan wọnyi di mimọ̀ fun Ọlọrun ni iṣẹ rẹ̀ gbogbo, lati igba ọjọ ìwa.

19. Njẹ ìmọràn temi ni, ki a máṣe yọ awọn ti o yipada si Ọlọrun lẹnu ninu awọn Keferi:

20. Ṣugbọn ki a kọwe si wọn, ki nwọn ki o fà sẹhin kuro ninu ẽri oriṣa, ati kuro ninu àgbere, ati kuro ninu ohun ilọlọrun-pa, ati kuro ninu ẹ̀jẹ.

21. Mose nigba atijọ sa ní awọn ti nwasu rẹ̀ ni ilu gbogbo, a ma kà a ninu sinagogu li ọjọjọ isimi.

22. Nigbana li o tọ́ loju awọn aposteli, ati awọn àgbagbà pẹlu gbogbo ijọ, lati yàn enia ninu wọn, ati lati ran wọn lọ si Antioku pẹlu Paulu on Barnaba: Juda ti a npè apele rẹ̀ ni Barsaba, ati Sila, ẹniti o l'orukọ ninu awọn arakunrin.

23. Nwọn si kọ iwe le wọn lọwọ bayi pe, Awọn aposteli, ati awọn àgbagbà, ati awọn arakunrin, kí awọn arakunrin ti o wà ni Antioku, ati ni Siria, ati ni Kilikia ninu awọn Keferi:

24. Niwọnbi awa ti gbọ́ pe, awọn kan ti o ti ọdọ wa jade lọ fi ọ̀rọ yọ nyin li ẹnu, ti nwọn nyi nyin li ọkàn po, wipe, Ẹnyin kò gbọdọ ṣaima kọ ilà, ati ṣaima pa ofin Mose mọ́: ẹniti awa kò fun li aṣẹ:

25. O yẹ loju awa, bi awa ti fi imọ ṣọkan lati yàn enia ati lati rán wọn si nyin, pẹlu Barnaba on Paulu awọn olufẹ wa.

26. Awọn ọkunrin ti o fi ẹmí wọn wewu nitori orukọ Oluwa wa Jesu Kristi.

27. Nitorina awa rán Juda on Sila, awọn ti yio si fi ọ̀rọ ẹnu sọ ohun kanna fun nyin.

28. Nitori o dara loju Ẹmi Mimọ́, ati loju wa, ki a máṣe dì ẹrù kà nyin, jù nkan ti a ko le ṣe alaiṣe wọnyi lọ:

Iṣe Apo 15