Iṣe Apo 15:13-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Lẹhin ti nwọn si dakẹ, Jakọbu dahùn, wipe, Ará, ẹ gbọ ti emi:

14. Simeoni ti rohin bi Ọlọrun li akọṣe ti bojuwò awọn Keferi, lati yàn enia ninu wọn fun orukọ rẹ̀.

15. Ati eyiyi li ọ̀rọ awọn woli ba ṣe dede; bi a ti kọwe rẹ̀ pe,

16. Lẹhin nkan wọnyi li emi o pada, emi o si tún agọ́ Dafidi pa ti o ti wó lulẹ; emi ó si tún ahoro rẹ̀ kọ́, emi ó si gbé e ró:

17. Ki awọn enia iyokù le mã wá Oluwa, ati gbogbo awọn Keferi lara ẹniti a npè orukọ mi,

18. Li Oluwa wi, ẹniti o sọ gbogbo nkan wọnyi di mimọ̀ fun Ọlọrun ni iṣẹ rẹ̀ gbogbo, lati igba ọjọ ìwa.

19. Njẹ ìmọràn temi ni, ki a máṣe yọ awọn ti o yipada si Ọlọrun lẹnu ninu awọn Keferi:

20. Ṣugbọn ki a kọwe si wọn, ki nwọn ki o fà sẹhin kuro ninu ẽri oriṣa, ati kuro ninu àgbere, ati kuro ninu ohun ilọlọrun-pa, ati kuro ninu ẹ̀jẹ.

21. Mose nigba atijọ sa ní awọn ti nwasu rẹ̀ ni ilu gbogbo, a ma kà a ninu sinagogu li ọjọjọ isimi.

Iṣe Apo 15