Paulu on Barnaba si sọ laibẹru pe, Ẹnyin li o tọ ki a kọ́ sọ ọ̀rọ Ọlọrun fun: ṣugbọn bi ẹ ti ta a nù, ẹ sì kà ara nyin si alaiyẹ fun iyè ainipẹkun, wo o, awa yipada sọdọ awọn Keferi.