22. Nwọn si wipe, Korneliu balogun ọrún, ọkunrin olõtọ, ati ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun, ti o si ni orukọ rere lọdọ gbogbo orilẹ-ede awọn Ju, on li a ti ọdọ Ọlọrun kọ́ nipasẹ angẹli mimọ́, lati ranṣẹ pè ọ wá si ile rẹ̀ ati lati gbọ́ ọ̀rọ li, ẹnu rẹ.
23. Nigbana li o pè wọn wọle, o si fi wọn wọ̀. Nijọ keji o si dide, o ba wọn lọ, ninu awọn arakunrin ni Joppa si ba a lọ.
24. Nijọ keji nwọn si wọ̀ Kesarea. Korneliu si ti nreti wọn, o si ti pè awọn ibatan ati awọn ọrẹ́ rẹ̀ timọtimọ jọ.
25. O si ṣe bi Peteru ti nwọle, Korneliu pade rẹ̀, o wolẹ li ẹsẹ rẹ̀, o si foribalẹ fun u.
26. Ṣugbọn Peteru gbé e dide, o ni, Dide; enia li emi tikarami pẹlu.
27. Bi o si ti mba a sọ̀rọ, o wọle, o si bá awọn enia pipọ ti nwọn pejọ.
28. O si wi fun wọn pe, Ẹnyin mọ̀ bi o ti jẹ ẽwọ̀ fun ẹniti iṣe Ju, lati ba ẹniti iṣe ara ilẹ miran kẹgbẹ, tabi lati tọ̀ ọ wá; ṣugbọn Ọlọrun ti fihàn mi pe, ki emi ki o máṣe pè ẹnikẹni li ẽwọ̀ tabi alaimọ́.
29. Nitorina ni mo si ṣe wá li aijiyàn, bi a ti ranṣẹ pè mi: njẹ mo bère, nitori kili ẹnyin ṣe ranṣẹ pè mi?
30. Korneliu si dahùn pe, Ni ijẹrin, mo nṣe adura wakati kẹsan ọjọ ni ile mi titi di akoko yi, si wo o, ọkunrin kan alaṣọ àla duro niwaju mi.