5. Ọ̀rọ̀ ayipo awọn enia ọlọkan ẽri ti kò si otitọ ninu wọn, ti nwọn ṣebi ọna si ere ni ìwa-bi-Ọlọrun: yẹra lọdọ irú awọn wọnni.
6. Ṣugbọn iwa-bi-Ọlọrun pẹlu itẹlọrùn ère nla ni.
7. Nitori a kò mu ohun kan wá si aiye, bẹni a kò si le mu ohunkohun jade lọ.
8. Bi a ba si li onjẹ ati aṣọ ìwọnyi yio tẹ́ wa lọrùn.
9. Ṣugbọn awọn ti nfẹ di ọlọrọ̀ a mã bọ́ sinu idanwò ati idẹkun, ati sinu wère ifẹkufẹ pipọ ti ipa-ni-lara, iru eyiti imã rì enia sinu iparun ati ègbé.
10. Nitori ifẹ owo ni gbòngbo ohun buburu gbogbo: eyiti awọn miran nlepa ti a si mu wọn ṣako kuro ninu igbagbọ́, nwọn si fi ibinujẹ pupọ̀ gún ara wọn li ọ̀kọ̀.
11. Ṣugbọn iwọ enia Ọlọrun, sá fun nkan wọnyi; ki o si mã lepa ododo, ìwa-bi-Ọlọrun, igbagbọ́, ifẹ, sũru, ìwa tutù.
12. Mã jà ìja rere ti igbagbọ́, di ìye ainipẹkun mu ninu eyiti a gbé pè ọ si, ti iwọ si ṣe ijẹwo rere niwaju ẹlẹri pupọ̀.
13. Mo paṣẹ fun ọ niwaju Ọlọrun, ti nsọ ohun gbogbo di ãye, ati niwaju Jesu Kristi, ẹni, niwaju Pontiu Pilatu, ti o jẹri ijẹwọ rere,
14. Ki iwọ ki o pa ofin mọ́ li ailabawọn, li ailẹgan, titi di ifarahàn Oluwa wa Jesu Kristi:
15. Eyiti yio fihàn ni igba tirẹ̀, Ẹniti iṣe Olubukún ati Alagbara na kanṣoṣo, Ọba awọn ọba, ati Oluwa awọn oluwa;