11. Ṣugbọn kọ̀ awọn opo ti kò dagba: nitoripe nigbati nwọn ba ti ṣe ifẹkufẹ lodi si Kristi, nwọn a fẹ gbeyawo;
12. Nwọn a di ẹlẹbi, nitoriti nwọn ti kọ̀ igbagbọ́ wọn iṣaju silẹ.
13. Ati pẹlu nwọn nkọ́ lati ṣe ọlẹ, lati mã kiri lati ile de ile; ki iṣe ọlẹ nikan, ṣugbọn onisọkusọ ati olofòfo pẹlu, nwọn a ma sọ ohun ti kò yẹ.
14. Nitorina mo fẹ ki awọn opo ti kò dagba mã gbeyawo, ki nwọn mã bímọ, ki nwọn ki o mã ṣe alabojuto ile, ki nwọn ki o máṣe fi àye silẹ rara fun ọtá na lati sọ̀rọ ẹ̀gan.
15. Nitori awọn miran ti yipada kuro si ẹhin Satani.