1. Tim 4:5-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Nitori a fi ọ̀rọ Ọlọrun ati adura yà a si mimọ́.

6. Bi iwọ ba nrán awọn ará leti nkan wọnyi, iwọ o jẹ iranṣẹ rere ti Kristi Jesu, ti a nfi ọrọ igbagbọ́ ati ẹ̀kọ rere bọ́, eyiti iwọ ti ntẹle.

7. Ṣugbọn kọ̀ ọrọ asan ati itan awọn agba obinrin, si mã tọ́ ara rẹ si ìwa-bi-Ọlọrun.

8. Nitori ṣíṣe eré ìdaraya ní èrè diẹ, ṣugbọn ìwa-bi-Ọlọrun li ère fun ohun gbogbo, o ni ileri ti aiye isisiyi ati ti eyi ti mbọ̀.

9. Otitọ ni ọrọ na, o si yẹ fun itẹwọgbà gbogbo.

10. Nitori fun eyi li awa nṣe lãlã ti a si njijakadi, nitori awa ni ireti ninu Ọlọrun alãye, ẹniti iṣe Olugbala gbogbo enia, pẹlupẹlu ti awọn ti o gbagbọ́.

11. Nkan wọnyi ni ki o mã palaṣẹ ki o si mã kọ́ni.

1. Tim 4