10. Nitori fun eyi li awa nṣe lãlã ti a si njijakadi, nitori awa ni ireti ninu Ọlọrun alãye, ẹniti iṣe Olugbala gbogbo enia, pẹlupẹlu ti awọn ti o gbagbọ́.
11. Nkan wọnyi ni ki o mã palaṣẹ ki o si mã kọ́ni.
12. Máṣe jẹ ki ẹnikẹni ki o gàn ewe rẹ; ṣugbọn ki iwọ ki o jẹ apẹrẹ fun awọn ti o gbagbọ́, ninu ọ̀rọ, ninu ìwa hihu, ninu ifẹ, ninu ẹmí, ninu igbagbọ́, ninu ìwa mimọ́.
13. Titi emi o fi de, mã tọju iwe kikà ati igbaniyanju ati ikọ́ni.
14. Máṣe ainani ẹ̀bun ti mbẹ lara rẹ, eyiti a fi fun ọ nipa isọtẹlẹ pẹlu ifọwọle awọn àgba.
15. Mã fiyesi nkan wọnyi; fi ara rẹ fun wọn patapata; ki ilọsiwaju rẹ ki o le hàn gbangba fun gbogbo enia.