1. Tim 3:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OTITỌ ni ọ̀rọ na, bi ẹnikan ba fẹ oyè biṣopu, iṣẹ rere li o nfẹ.

2. Njẹ biṣopu jẹ alailẹgan, ọkọ aya kan, oluṣọra, alairekọja, oniwa yiyẹ, olufẹ alejò ṣiṣe, ẹniti o le ṣe olukọ.

3. Ki o má jẹ ọmuti, tabi onijà, tabi olojukokoro, bikoṣe onisũru, ki o má jẹ onija, tabi olufẹ owo;

4. Ẹniti o kawọ ile ara rẹ̀ girigiri, ti o mu awọn ọmọ rẹ̀ tẹriba pẹlu ìwa àgba gbogbo;

5. (Ṣugbọn bi enia kò ba mọ̀ bi ã ti ṣe ikawọ ile ara rẹ̀, on o ha ti ṣe le tọju ijọ Ọlọrun?)

6. Ki o má jẹ ẹni titun, kí o má bã gbéraga, ki o si ṣubu sinu ẹbi Èṣu.

7. O si yẹ kí o ni ẹri rere pẹlu lọdọ awọn ti mbẹ lode: kí o má ba bọ sinu ẹ̀gan ati sinu idẹkun Èṣu.

1. Tim 3