12. Ṣugbọn emi kò fi aṣẹ fun obinrin lati mã kọ́ni, tabi lati paṣẹ lori ọkunrin, bikoṣepe ki o dakẹjẹ.
13. Nitori Adamu li a kọ́ dá, lẹhin na, Efa.
14. A kò si tàn Adamu jẹ, ṣugbọn obinrin na, nigbati a tàn a, o ṣubu sinu ẹ̀ṣẹ.
15. Ṣugbọn a o gbà a là nipa ìbimọ rẹ̀, bi nwọn ba duro ninu igbagbọ́ ati ifẹ, ati ìwa mimọ́ pẹlu ìwa airekọja.