1. Tim 2:11-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Jẹ ki obinrin ki o mã fi idakẹjẹ ati itẹriba gbogbo kọ́ ẹkọ́.

12. Ṣugbọn emi kò fi aṣẹ fun obinrin lati mã kọ́ni, tabi lati paṣẹ lori ọkunrin, bikoṣepe ki o dakẹjẹ.

13. Nitori Adamu li a kọ́ dá, lẹhin na, Efa.

14. A kò si tàn Adamu jẹ, ṣugbọn obinrin na, nigbati a tàn a, o ṣubu sinu ẹ̀ṣẹ.

15. Ṣugbọn a o gbà a là nipa ìbimọ rẹ̀, bi nwọn ba duro ninu igbagbọ́ ati ifẹ, ati ìwa mimọ́ pẹlu ìwa airekọja.

1. Tim 2