1. Tim 2:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NITORINA mo gbà nyin niyanju ṣaju ohun gbogbo, pe ki a mã bẹ̀bẹ, ki a mã gbadura, ki a mã ṣìpẹ, ati ki a mã dupẹ nitori gbogbo enia;

2. Fun awọn ọba, ati gbogbo awọn ti o wà ni ipo giga; ki a le mã lo aiye wa ni idakẹjẹ ati pẹlẹ ninu gbogbo ìwa-bi-Ọlọrun ati ìwa agbà.

3. Nitori eyi dara o si ṣe itẹwọgbà niwaju Ọlọrun Olugbala wa;

4. Ẹniti o nfẹ ki gbogbo enia ni igbala ki nwọn si wá sinu ìmọ otitọ.

1. Tim 2