7. Nwọn nfẹ ṣe olukọ ofin; òye ohun ti nwọn nwi kò yé wọn, tabi ti ohun ti nwọn ntẹnumọ́.
8. Ṣugbọn awa mọ̀ pe ofin dara, bi enia ba lò o bi ã ti ilo ofin;
9. Bi a ti mọ̀ eyi pe, a kò ṣe ofin fun olododo, bikoṣe fun awọn alailofin ati awọn alaigbọran, fun awọn alaiwa-bi-Ọlọrun ati awọn ẹlẹṣẹ, fun awọn alaimọ́ ati awọn ẹlẹgan, fun awọn apa-baba ati awọn apa-iya, fun awọn apania,
10. Fun awọn àgbere, fun awọn ti nfi ọkunrin ba ara wọn jẹ́, fun awọn ají-enia tà, fun awọn eke, fun awọn abura eke, ati bi ohun miran ba si wà ti o lodi si ẹkọ́ ti o yè koro,
11. Gẹgẹ bi ihinrere ti ogo Ọlọrun olubukún, ti a fi si itọju mi.
12. Mo dupẹ lọwọ Ẹniti o fun mi li agbara, ani Kristi Jesu Oluwa wa, nitoriti o kà mi si olõtọ ni yiyan mi si iṣẹ rẹ̀;
13. Bi mo tilẹ jẹ asọ ọ̀rọ-odì lẹkan rí, ati oninunibini, ati elewu enia: ṣugbọn mo ri ãnu gbà, nitoriti mo ṣe e li aimọ̀ ninu aigbagbọ.