1. NITORINA nigbati ara wa kò gba a mọ́, awa rò pe o dara ki a fi awa nikan sẹhin ni Ateni;
2. Awa si rán Timotiu, arakunrin wa, ati iranṣẹ Ọlọrun ninu ihinrere Kristi, lati fi ẹsẹ nyin mulẹ, ati lati tù nyin ninu niti igbagbọ́ nyin:
3. Ki a máṣe mu ẹnikẹni yẹsẹ nipa wahalà wọnyi: nitori ẹnyin tikaranyin mọ̀ pe a ti yàn wa sinu rẹ̀.
4. Nitori nitõtọ nigbati awa wà lọdọ nyin, a ti nsọ fun nyin tẹlẹ pe, awa ó ri wahalà; gẹgẹ bi o si ti ṣẹ, ti ẹnyin si mọ̀.
5. Nitori eyi, nigbati ara mi kò gba a mọ́, mo si ranṣẹ ki emi ki o le mọ igbagbọ́ nyin ki oludanwò nì má bã ti dan nyin wo lọnakọna, ki lãlã wa si jẹ asan.
6. Ṣugbọn nisisiyi ti Timotiu ti ti ọdọ nyin wá sọdọ wa, ti o si ti mu ihinrere ti igbagbọ́ ati ifẹ nyin wá fun wa, ati pe ẹnyin nṣe iranti wa ni rere nigbagbogbo, ẹnyin si nfẹ gidigidi lati ri wa, bi awa pẹlu si ti nfẹ lati ri nyin:
7. Nitori eyi, ará, awa ni itunu lori nyin ninu gbogbo wahalà ati ipọnju wa nitori igbagbọ́ nyin:
8. Nitori awa yè nisisiyi, bi ẹnyin ba duro ṣinṣin ninu Oluwa.
9. Nitori ọpẹ́ kili awa le tún ma dá lọwọ Ọlọrun nitori nyin, fun gbogbo ayọ̀ ti awa nyọ̀ nitori nyin niwaju Ọlọrun wa;