10. Ẹnyin si li ẹlẹri, ati Ọlọrun pẹlu, bi awa ti wà lãrin ẹnyin ti o gbagbọ́ ni mimọ́ iwà ati li ododo, ati li ailẹgan:
11. Gẹgẹ bi ẹnyin si ti mọ̀ bi awa ti mba olukuluku nyin lo gẹgẹ bi baba si awọn ọmọ rẹ̀, a ngba nyin niyanju, a ntu nyin ninu, a si kọ́,
12. Ki ẹnyin ki o le mã rìn ni yiyẹ Ọlọrun, ẹniti o npè nyin sinu ijọba ati ogo On tikararẹ.
13. Nitori eyi li awa ṣe ndupẹ lọwọ Ọlọrun pẹlu li aisimi, pe nigbati ẹnyin gba ọ̀rọ ti ẹnyin gbọ lọdọ wa, ani ọ̀rọ Ọlọrun, ẹnyin kò gbà a bi ẹnipe ọ̀rọ enia, ṣugbọn gẹgẹ bi o ti jẹ nitõtọ, bi ọ̀rọ Ọlọrun, eyiti o ṣiṣẹ gidigidi ninu ẹnyin ti o gbagbọ́ pẹlu.
14. Nitori, ará, ẹnyin di alafarawe awọn ijọ Ọlọrun ti mbẹ ni Judea, ninu Kristi Jesu: nitoripe ẹnyin pẹlu jìya iru ohun kanna lọwọ awọn ara ilu nyin, gẹgẹ bi awọn pẹlu ti jìya lọwọ awọn Ju:
15. Awọn ẹniti o pa Jesu Oluwa, ati awọn woli, nwọn si tì wa jade; nwọn kò si ṣe eyiti o wu Ọlọrun, nwọn si wà lodi si gbogbo enia: