8. O si ṣe, li ọjọ keji, nigbati awọn Filistini de lati bọ́ nkan ti mbẹ lara awọn ti o kú, nwọn si ri pe, Saulu ati awọn ọmọ rẹ̀ mẹta ṣubu li oke Gilboa,
9. Nwọn si ke ori rẹ̀, nwọn si bọ́ ihamọra rẹ̀, nwọn si ranṣẹ lọ si ilẹ Filistini ka kiri, lati ma sọ ọ nigbangba ni ile oriṣa wọn, ati larin awọn enia.
10. Nwọn si fi ihamọra rẹ̀ si ile Aṣtaroti: nwọn si kàn okú rẹ̀ mọ odi Betṣani.
11. Nigbati awọn ara Jabeṣi-Gileadi si gbọ́ eyiti awọn Filistini ṣe si Saulu;
12. Gbogbo awọn ọkunrin alagbara si dide, nwọn si fi gbogbo oru na rìn, nwọn si gbe okú Saulu, ati okú awọn ọmọbibi rẹ̀ kuro lara odi Betṣani, nwọn si wá si Jabeṣi, nwọn si sun wọn nibẹ.