1. AWỌN Filistini si ba Israeli jà: awọn ọkunrin Israeli si sa niwaju awọn Filistini, awọn ti o fi ara pa sì ṣubu li oke Gilboa.
2. Awọn Filistini si nlepa Saulu ati awọn ọmọ rẹ̀ kikan; awọn Filistini si pa Jonatani, ati Abinadabu, ati Melkiṣua, awọn ọmọ Saulu.
3. Ijà na si buru fun Saulu gidigidi, awọn tafàtafa si ta a li ọfà, o si fi ara pa pupọ li ọwọ́ awọn tafàtafa.