Dafidi si ba igba ọkunrin ti o ti rẹ̀ jù ati tọ̀ Dafidi lẹhin, ti on ti fi silẹ li odò Besori: nwọn si lọ ipade Dafidi, ati lati pade awọn enia ti o pẹlu rẹ̀: Dafidi si pade awọn enia na, o si ki wọn.