36. Abigaili si tọ̀ Nabali wá, si wõ, on si se asè ni ile rẹ̀ gẹgẹ bi ase ọba; inu Nabali si dùn nitoripe, o ti mu ọti li amupara; on kò si sọ nkan fun u, diẹ tabi pupọ: titi di imọlẹ owurọ.
37. O si ṣe; li owurọ, nigbati ọti na si dá tan li oju Nabali, obinrin rẹ̀ si rò nkan wọnni fun u, ọkàn rẹ̀ si kú ninu, on si dabi okuta.
38. O si ṣe lẹhin iwọn ijọ mẹwa, Oluwa lù Nabali, o si kú.
39. Dafidi si gbọ́ pe Nabali kú, o si wi pe, Iyin ni fun Oluwa ti o gbeja gigàn mi lati ọwọ́ Nabali wá, ti o si da iranṣẹ rẹ̀ duro lati ṣe ibi: Oluwa si yi ikà Nabali si ori on tikalarẹ̀. Dafidi si ranṣẹ, o si ba Abigaili sọ̀rọ lati mu u fi ṣe aya fun ara rẹ̀.
40. Awọn iranṣẹ Dafidi si lọ sọdọ Abigaili ni Karmeli, nwọn si sọ fun u pe, Dafidi rán wa wá si ọ lati mu ọ ṣe aya rẹ̀.
41. O si dide, o si dojubolẹ, o si wipe, Wõ, jẹ ki iranṣẹbinrin rẹ ki o jẹ iranṣẹ kan lati ma wẹ ẹsẹ awọn iranṣẹ oluwa mi.
42. Abigaili si yara, o dide, o si gun kẹtẹkẹtẹ, awọn iranṣẹbinrin rẹ̀ marun si tẹle e lẹhin; on si tẹle awọn iranṣẹ Dafidi, o si wa di aya rẹ̀.