1. Sam 20:7-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Bi o ba wipe, O dara, alafia mbẹ fun iranṣẹ rẹ: ṣugbọn bi o ba binu pupọ, njẹ ki iwọ ki o mọ̀ daju pe buburu ni o nrò ninu rẹ̀.

8. Iwọ o si ṣe ore fun iranṣẹ rẹ, nitoripe iwọ ti mu iranṣẹ rẹ wọ inu majẹmu Oluwa pẹlu rẹ; ṣugbọn bi ìwa buburu ba mbẹ li ọwọ mi, iwọ tikararẹ pa mi; ẽṣe ti iwọ o fi mu mi tọ baba rẹ lọ?

9. Jonatani si wipe, Ki eyini ki o jina si ọ: nitoripe bi emi ba mọ̀ daju pe baba mi npete ibi ti yio wá sori rẹ, njẹ emi le iṣe alaisọ ọ fun ọ bi?

10. Nigbana ni Dafidi wi fun Jonatani pe, Tani yio sọ fun mi? tabi yio ti ri bi baba rẹ ba si fi ìjãnu da ọ lohùn.

11. Jonatani si wi fun Dafidi pe, Wá, jẹ ki a jade lọ si pápá. Awọn mejeji si jade lọ si pápá.

1. Sam 20