39. Ọmọdekunrin na kò si mọ̀ nkan: ṣugbọn Jonatani ati Dafidi li o mọ̀ ọ̀ran na.
40. Jonatani si fi apó ati ọrun rẹ̀ fun ọmọdekunrin rẹ̀, o si wi fun u pe, Lọ, ki o si mu wọn lọ si ilu.
41. Bi ọmọdekunrin na ti lọ tan, Dafidi si dide lati iha gusu, o si wolẹ, o si tẹriba lẹrinmẹta: nwọn si fi ẹnu ko ara wọn li ẹnu, nwọn si jumọ sọkun, ekini keji wọn, titi Dafidi fi bori.
42. Jonatani si wi fun Dafidi pe, Ma lọ li alafia, bi o ti jẹ pe awa mejeji ti jumọ bura li orukọ Oluwa, pe, Ki Oluwa ki o wà lãrin emi ati iwọ, lãrin iru-ọmọ mi ati lãrin iru-ọmọ rẹ lailai. On si dide, o si lọ kuro: Jonatani si lọ si ilu.