35. O si ṣe, li owurọ ni Jonatani jade lọ si oko li akoko ti on ati Dafidi ti fi si, ọmọdekunrin kan si wà pẹlu rẹ̀.
36. O si wi fun ọmọdekunrin rẹ̀ pe, sare, ki o si wá ọfà wọnni ti emi o ta. Bi ọmọde na si ti nsare, on si tafa rekọja rẹ̀.
37. Nigbati ọmọdekunrin na si de ibi ọfà ti Jonatani ta, Jonatani si kọ si ọmọdekunrin na, o si wipe, ọfà na ko ha wà niwaju rẹ bi?
38. Jonatani si kọ si ọmọdekunrin na pe, Sare, yara, máṣe duro. Ọmọdekunrin Jonatani si ṣa ọfà wọnni, o si tọ̀ oluwa rẹ̀ wá.
39. Ọmọdekunrin na kò si mọ̀ nkan: ṣugbọn Jonatani ati Dafidi li o mọ̀ ọ̀ran na.
40. Jonatani si fi apó ati ọrun rẹ̀ fun ọmọdekunrin rẹ̀, o si wi fun u pe, Lọ, ki o si mu wọn lọ si ilu.
41. Bi ọmọdekunrin na ti lọ tan, Dafidi si dide lati iha gusu, o si wolẹ, o si tẹriba lẹrinmẹta: nwọn si fi ẹnu ko ara wọn li ẹnu, nwọn si jumọ sọkun, ekini keji wọn, titi Dafidi fi bori.