19. Bi iwọ ba si duro ni ijọ mẹta, nigbana ni iwọ o si yara sọkalẹ, iwọ o si wá si ibiti iwọ gbe ti fi ara rẹ pamọ si nigbati iṣẹ na wà lọwọ, iwọ o si joko ni ibi okuta Eseli.
20. Emi o si ta ọfà mẹta si ìha ibẹ̀ na, gẹgẹ bi ẹnipe mo ta si àmi kan.
21. Si wõ, emi o ran ọmọde-kọnrin kan pe, Lọ, ki o si wá ọfa wọnni. Bi emi ba tẹnu mọ ọ fun ọmọkunrin na, pe, Wõ, ọfa wọnni wà lẹhin rẹ, ṣà wọn wá; nigbana ni iwọ o ma bọ̀; nitoriti alafia mbẹ fun ọ, kò si ewu; bi Oluwa ti wà.
22. Ṣugbọn bi emi ba wi bayi fun ọmọde-kọnrin na pe, Wõ ọfa na mbẹ niwaju rẹ; njẹ ma ba tirẹ lọ; Oluwa li o rán ọ lọ.
23. Niti ọ̀rọ ti emi ati iwọ si ti jumọ sọ, wõ, ki Oluwa ki o wà larin iwọ ati emi titi lailai.
24. Bẹ̃ni Dafidi sì pa ara rẹ̀ mọ li oko; nigbati oṣu titun si de, ọba si joko lati jẹun.